Thursday 12 September 2024

ASIRI EWE ATI EGBO



1. 

AGBO GBOGBONISE ARUN TABI AISAN EYIKEYI NINU ARA ENIA ( IRU AISAN TABI AARUN YOWU KOJE..) 


Mose iba fun oni sababi ise nla yii, Dr al-imam Babatunde*lati ilu Benin republic. Ọlọhun je ki Ari baba PE (Allahumo Ameen)


Ise na re:-  Egbo ogbo tutu, egbo sagere tutu, enu opiye tutu, oro adete, oro agogo, Aidan onigun, iseta, Eku asin tutu, Oga gbigbe ao gesi wewe ao ko dasinu keg 2.5Litres tabi 5Litres ao wa ko orogbo tutu mokanla (11) tepotepo, atare odidi mokanla (11), obi abata oloju meta mokanla (11), obi gbanja mokanla (11) sinu keg naa aowa da epo oyinbo kerosine igo kan ati abo sinu re, ao tun da adii dudu igo kan abo si, aowa depa aolo ri mole fun 16days. Leyin eyi ao lo hu jade.

 

Lilore: Ao ma fun alaisan ni sibi imuko nla meji mu laro ati lale tabi ilaji gaasi kan ....

kosi Arun tabi aisan tiko kapa. Odaju amo Olorun daju ju gbogbo e lo.

 Alfa Abdul Ramon


2. 

OGUN FUN ITO-SUGAR 

Epo Ako-Isu topo, Gbogbo Iye Ati Ifun Akuko-Adiye Ibile Kan, Odidi-Atare Kan. Ao 

Jo Won Po, AO Lo Ebu yen Kuna-Dada. AO Ma Fi OMI-TUTU (OrdinaryWater) 

Tabi EKO-TUTU Lo Ebu Na Deede.

 By Alfa Abdul Ramon


3.

OGUN IDA. EJE TABI IGBE EJE

 Ao ge igi ôgêdê eyi keyi ti yio gun diê, ao gun ninu odo , ao wa fún omi toba jade lara rẹ síbi kan, ki êniyen maa mu laro-lalê , koto pe ọjọ meta,koni yagbê êjê yen mọ insha Allah.             

By Alfa kamoldeen Akeujaye


4. 

OGUN ONIGBA-MEJI 

( ki eyan maabi koma yagbê niwon npe ni onigba-meji).                 Ao lọ ge igi ôgêdê eyikeyi, ao gun kuna ninu odo, omi toba jade nibe, ao fi gbo ewe êfirin nla , ao sê idoti rê kuro , ẹjẹ kia rô sinu keg kan tabi ike kan , ao gbe toju ...... Tia bari eni to nyagbê to nbi , ẹjẹ kia fún ni Gas kan tabi meji , pẹlu ogo olorun, yio stop , odaju ooo ......

By Alfa kamoldeen Akeujaye


5.

AWORO ITAJA TIO DAJU

Ori oka toni ase, Eweaje/sefunsefun, Sawerepepe, Tannapowo, Sinkimidin, 

Awoyoyo/inabo, Ewe oriji, Ajeobale. Ao gun gbogbo ewe yi papo ni tutu pelu ose 

abuwe, ao fi ori oka yen tele ike tia mako ose nasi, ao wako ose na lelori ao ma 

fi we tabi fifowo, tabi ma fiwon shop ati oja wa.

 By Alfa Abdul Ramon


6.

ALEKO (MANPOWER) FUN OKUNRIN

Ogede-Agbagba Dudu (AO Bo Epo Ara Re Kuro), Bara-NlaKan (AO Bo Epo Ara Re 

Kuro), Sugar-Onikoro (Cubes-Sugar, Not Dangote O) -20pcs. A O Ko Won Sinu 

Kotopo Tabi Ike-Olomori To Fe Die. AO Wa Fi OMIDUN Re (Soak) Won Po Fun 

3 Days. A O Ma Mu Ni GAASI (Shot) Kan Dede. OLOHUN NIKAN NI OLUWOSAN 

TODAJU.


7.

OGUN FUN ITO-SUGAR

Epo Ako-Isu topo, Gbogbo Iye Ati Ifun Akuko-Adiye Ibile Kan, Odidi-Atare Kan. Ao 

Jo Won Po, AO Lo Ebu yen Kuna-Dada. AO Ma Fi OMI-TUTU (OrdinaryWater) 

Tabi EKO-TUTU Lo Ebu Na Deede.

 By Alfa Abdul Ramon


7.

ASIRI FI AYE GBAMI NIBI TIA BAWA

 Ori oka kan,ori ẹyẹ asa kan, awọ êkun diê,ewe Ejirin, odidi atare kan, ao ko gbogbo eroja yi sinu apê, ao fi ewe Ejirin bo môlê,ao jo, ao rọ sinu igo funfun kan .......                 

LILORÊ:

Ao ma bu si atêlêwô alaafia diẹ diẹ,ao ma pe ôfô rẹ sí , ao wa fi omi lo.......                 

OFORE:-

Mode ki aye gbami , gbogbo igi oko ni ntêriba fun Ejirin.        

 --Mode ki aye gbami , gbogbo ẹyẹ oko ni ntêriba fún asha.         

 --Mode ki aye gbami , gbogbo ejo Igbo ni ntêri fún ôka.             

  --Mode ki aye gbami , oso ni- ajê ni - woly ni - okunrin ati obinrin, bê ni kiwon ma tẹriba fun emi L ọmọ L, gbogbo eni toba foju kanmi ati gbogbo aladugbo mi , bẹ ni kiwọn ma tẹriba fúnmi lati onilô........ 

Ao se adura sí bia se fẹ, ao fi omi lo....... Odaju púpọ


8.

EYONU ASINA OWO TOJUDA 

Ako alangba mesan abo alangba mesan ewe tude idi mesan egbo tude idi mesan odidi

atare mesan aojo gbogbo re papo ao lo kuna Dada ao ro sinu igo funfun ao mafi fokomu

tabi oyin tabi nkan tioba wuwa lo

NOTE : Ao fi epo pupa yika aro oooo..


9.

BI ARA OBINRIN KOBAYA SI IBALOPO

Egbo dongoyaro, egbo agbayun, ao ge ila die si, ao fi emu da lagbo, bi kobasi oko wa ni ile, kama mu agbo yio. Ki ise maba di ise alagbafo.


10.
AWURE ASINA KIAKIA

opolo ooye meta odindi atare meta aojo 
papo,egbo lapalapa funfun ati egbo lapalapa pupa,ao gesi wewe aofi oti ki lagbo sinu igo kan ao wada ebu ti ajo yen sinu oti ti aki yen,ao mamu lararo Odaju.

11.
OGUN KI AMALE KO ARUN LARA OBINRIN

Adigbonnoku Kan, irun ori agbado ati horo eyo atare Kan ao lo papo ao fi sin
gberen Kan si ori oko wa, koda gan ti magun bawa lara obinrin naa oko wa ko ni

12.
OGUN EYONU GBAYE

ewe oriji topo, ewe isaju, ewe anu, ewe ajeobale topo, ori olongbo tonirun kan, eso laara
pupa topo, aadun jije topo, odidi atare kan, aojo gbogbo re po, lilore, aoma da sibi imuko
kan sinu igo schnapps kan pelu peak milk kan, eniyan pupo lelo


13.
OGUN IKO ASMAH TABI  IKO AWUGBE EYIKEYI IKO TI O YA WERE TI KI JE KI ENIYAN RI ORUN SUN

Ao wà ògùṣọ̀ ti anfi nda ina ti won ma hùn le mọn ara ògiri ní oko yen ao mun bi meji ao sún nínú ina boya ina igi tabi gas ⛽ tabi coal pot 🍲 ao sun jona ti gbogbo re yio di etu oògùn sungbon kò gbudo ru èéfín kánkan mon ao wà lọ ní ori olo ki o kùnà daada ao wa da diẹ nínú rẹ si inu oyin ojúlówó ao má là ni èèmeta lójoojúmó Títí ìkọ yi yóò fi lo patapata.

By Alfa kamoldeen Akeujaye

14.
ELEYI NI OOGUN IKO EYI KEYI TO DAJU

Epo  - ori  - adi eyan - erun alamô :.  
Ṣíṣe rê: 
Ao da adi , epo ati ori sinu pot kan , ao gbe lena, ao wa da erun alamô yen si, ao se jina dada..... Ao sọ kalẹ,toba tutu tan ao rọ sinu ike kan ,ao ma mu diẹ diẹ ni êêmeta lojumô......  Arọ -osan - alê.             By Alfa kamoldeen Akeujaye

14.
FUN ENI TI KOBA RI OORUN SUN

Elo wa epo Obo to finmu dada, ao gun ti koni kuna, ao ko sinu ike kan ,ao bù omi sii,ki enina maa mu gaz kan toba fẹ sun lalẹ..... Odaju                                                                 *By Alfa kamoldeen Akeujaye*

A o gbo ewe ewuro, ewe efinrin ati ewe dongoyaro die papo. A o wa fi kohun bilala die si, a o tun wa lo alubosa elewe meta pelu aayu ati garlic die. A o wa da papo mo ra won si nu Ike bottle water kan. LEYIN ojo keji, ki a jin po daada, agbalagba sibi imuko meta lojumo, omode sibi kan.
 By Alfa Abdul Ramon

15.
IFA IFAA ORETE OTURA ONIFAA

 EYELE FUNFUN KAN ao ge si (16)
IGBIN AGBONU KAN ao ge si (16)
ERAN ELEDE eyi ti ko leegun, ao ge si (16)
EWE AKINSAN, EWE SEFUNSEFUN, EWE ETIPONLA. Ao lo gbogbo ewe yi po Mo iyere, ao se lobe (lepo niyo). Ti o ba jina tan, ao so sori osuka. Ao fi iyereosun te Ifa " OSE IRETE OTURA"
Akola romi, aromi gbede gbede. Ifa lo mun ese Oro wo ile mi. Ifa iwo lomu ese Oro wole alara, ifa iwo lomu ese Oro wole ajero, ti ajero fi njoba. Ifa iwo lomu ese Oro wole orangun ile Ila, oun ni orangun se di oba. Ifa iwo lomu ese Oro wole oloja merindinlogun, ko to di oba.  Ifa o to ge, ki o wa fi ese Oro wole mi kiakia. Akinsan jeki o san mi, kin ni gbogbo ire aiye, nitori gbogbo ara ni SEFUNSEFUN fi n se owo. ETIPONLA abifa gbuuru, Ifa owo nlanla, Ifa ile nlala, nitori apa mejeeji ni eiyele fi n ko re wole. Gbede gbede ni ti ERAN ELEDE, ki o demi fun owo, ki o demi fun omo. Bi IGBIN ba ji, ajifa ile. Ki emi lagbaja omo lagbaja jifa owo nlala loni lowo okunrin, lowo obinrin o. 

 16.
OSHOLẸ OWO TODAJU

Aowa ewe sawerepepe púpọ oojọ, ẹyẹ kowe oloridudu kan, odidi atare nla kan. Ao fi ewe yii diẹ su osuka tẹlẹ apẹ ijogun yìí, ao wa gbe ẹyẹ le lori pẹlu odidi atare nla kan, ào tun su ewe yoku losuka, ào gbe le lori, ào wa jo pọ. Ào lọ kunna daadaa, ào wa rò sinu igo funfun nla kan. Ao ma fifọ ẹkọ tutu mu laararo. Odaju pupọ. 

*ALFA KAMOLDEEN AKEUJAYE*


17.
 AWORO ITAJA todaju
 ASEJE OSHOLE TODAJU

Ewe aje ojoo aolo lotoo
iyere aolo 
Ewe anu aolo lotoo
Ewe sawerepepe aolo lotoo
Iru isebe aolo lotoo 

Agbebo adire aopa aowa gesii 16 gbogbo awon ewe tii atiloyii aowa faa sinu isasun tuntun leyin naa ao se lepo niyo tii obajina tan aoso sorii osuka aso funfun ao wasadura sii aokoje niii ihoho omo luabii

Ti aba loo yo jẹ fún wa laṣẹ èdùmàrè.

18.
ISE ANU TO SISE FUN ASIRI BIBO

 A o wa ileke irun, ileke ifa, abere, eepo obo
SISE RE:- a o gun gbogbo re Kuna daada, a o Fi Omi awamaridi kan Po mo ose dudu tabi ose GANA, a o kosi Inu akaragba agban na.
LILO RE:- a o mafiwa pelu gbolohun re,
ITUN LONI KI E FI OHUN RERE TUNMISE, IFA LONI KI E FI OHUN RERE FAMI MORA, ONA TOMI BAWONU AGBON KOYE ENIKAN, KI ASIRI MI MA SE TU LOJU OMO ARAYE KI NRI ANU GBA NI GBOGBO ONA A O MA FI WA LARO LARO.

 19.
OSE ANU 

walahi unkan ise yii kere pupo sugbon ise nla ni.... ose dudu 
ati ewe ola, ao gun ewe ola yen kunaa daadaa ao waa po mo 
ose dudu ao maa fi we ni every8 wednesday, dakun ma se we 
ose yii ni ojo kijo sugbon wednesday... ti enia baa fe lo sin 
owo lowo enia kan, ki iru eni bayi fi ose yii fo owo mejeji ati 
ese mejeji ki o to lo baa eni naa, wednesday ni lilo re o. iwo ti 
o baa se aigboro ti o lo we ni ojo ti o baa wu e.

20.
OSOLE OWO TODAJU

Odidi musu kan, ewe orijin topo die, odidi atare kan, ao du musu yen sinu agbada, ao la musu yen ni inu, ao fi atare bo inu re, ao ko ewe yen sinu e, ao da iru woro naa sinu e, ao ko ewe orijin le, ao wa jo. Ao ma lo pelu omi aye lararo tabi lalale

21.
OSE ANU NLA TO DAJU GIDI GAN TEXTED AND CONFIRM WORK

✍️Eran elede oojo tiko ni egun ati awo lara basi kan, afara oyin die, ewe onitikuti oojo(ewe tomato lon je be o), ewe orijin oojo, ose dd tabi ghana, ao gun papo daadaa ti yio kunna, ao po ose mo, ao ko sinu ike ff kan, ao mafi we lararo kia to jade nile, o daju gan


22.
ISOYE OMODE TABI AGBA 

Akuko adie funfun . totiko dada 
Aopa sinu ape .aoko gbogbo tinure sinu ape na .
Aotu gbogbo iye abiyare na sibe .
Aoloja eso ako ibepe .tikokonle aokosilori leyin tatige ori adie yi na si aojopo mon odidi atare kon 
Aolo kuna dada 
  Lilore .aoda sinu oyin 
Opo omo lolelo

23.
IMULE AWON AGBA

 idaba eyin adiẹ meta-itanna akọ ibepe topo,  odidi atare kan...... Ao fi eyin meteeta tẹlẹ apẹ,ao ko itanna akọ ibepe sí , ao fi odidi atare kan le lori,ao jopo..... Ao ma fi epo pupa la sun ni alaalê pẹlu ofore:  mo bọ lọwọ aye (3times), iana idaba adiê bọ lọwọ aye,           -mo bọ lọwọ aye (3times) itana akọ ibepe bọ lọwọ kumọ , oso ni ,aje ni , lẹbọ lóògùn ni , kiê mase fi aburu se emi (L ọmọ L) , ao ma fisi ọwọ wa diẹ diẹ, ao ma bu epo pupa si,ao ma la tia bafe sun lalẹ..... Odaju

24.
IJU OBINRIN

 Osê soda, e bami jo, ki êniyen mafi f'okọ tutu mu laro laro

25.
BIBO ASIRI

Ewe Ako ibepe.ataijosi 16,Edo malu,a ma ge si 21.lepo ni yio.ori osuka Lati ma je aseje na .a o mu oti lord lori

26.
TURARI ATUDE /ASINA TI ONA FI NSI LAARIN ỌJỌ MÉJE

Okete Tutu kan, iseta pupo, ewe obiba, ewe labelabe, eru Alamo pupo, imi ojo, Alubosa elewe, etu ibon original

 ṢÍṢE RẸ

Ao gun awọn èròjà yi lotooto ti ko gbudọ pade ara won ninu odo , ao wa tẹ aṣọ funfun kan sile sinu ile , lori aso funfun yi ni gbogbo awọn èròjà yi a ti pàdé ,ao wa fi ọwọ́ roo gbogbo èròjà tí a gun yi papó daada lori aṣọ funfun yi , ao saa sinu ile bẹ ti yóò fi gbe. A o ma fin Nina pelu adua. Odaju.

No comments:

Post a Comment