Thursday, 12 September 2024

ERO ABILU

 Kinni àwa Yoruba npe ni Abilu? 


Abilu jẹ́ nkan asasi, aransi , epe tabi ègún.


 Wọ́n máa ń rán Abilu si ènìyàn , bẹ́ẹ̀ni  èèyàn a maa fi ara koo latara àfọwọ́fa tabi ègún lati ọdọ ẹnikẹ́ni. 


Bi abilu bawa lara Ọjọgbọn , gbogbo nnkan ni yóò má lọ lódìlódì fún olúwa rẹ . 


Orisirisi nkan ni yóò sì máa ṣẹlẹ̀. 


 Àwọn oògùn ìsàlẹ̀ kápá èyíkéyì Abilu tí a bafi orí koo.


1 ẹ̀rọ̀ àbìlù 


1. Ewé awẹdẹwẹrisa

2. Ewé tude

3. Eepo ọbọ 

4. Egbò túdè 

5. Ewé alupaida funfun 

6. Eepo igi ńlá 

7. Ata ìjọsì díẹ̀ 


 Síse rẹ :

Ao gun gbogbo rẹ papọ, ao pomọ ọsẹ dudu, ẹ̀jẹ̀ ẹyẹlé ni aofi poo dáàda. 


 Lilo rẹ :

Ao máfi Ọbẹ̀  bù ọ̀sẹ̀ yí sori kaninkanin iwẹ tí a bá fẹ́ wẹ ọsẹ yi ni ararọ . 

Omi gbígbóná lao maafi  wẹ laraarọ. 


 2 ẹ̀rọ̀ àbìlù 


1. Ewé arojoku 

Eku asin gbigbe

Ọga ibilẹ gbígbẹ kan

Odindi atare kan 

Jijo lẹtu. 

Ao pomọ ọsẹ dudu. Ao bu die sinu ọtí , ao maa mu.  Gbogbo abilu naa lào ya dànù mọ igbẹ wa.


 3 ẹ̀rọ̀ àbìlù 


1. Ewé agogo igun

Ao lo kuna, ao pomọ ọ̀sẹ̀ dudu, ao lọfi fọ orí wa nikan si odò to nsan pẹ̀lú gbólóhùn yii:

 Mo tẹ ori mi wọrọkọ 

Mo wẹ ibi orí mi dànù loni, mo tidi agogo igun láti òní lọ. 


Ao maase àdúrà titi ti aofi wẹ ọsẹ yi tan. 

Ao sọ kaninkanin naa sínú odo tí abati fọ ori wa tan.


Ọlọ́run yoo gbawa lọ́wọ́ ogun abilu, ṣùgbọ́n ẹ jeki awa naa maa sọra .


 4. oògùn atude tó dájú bí ikú ni yìí.


Àwọn atude tí yóò bẹ̀rẹ̀ isẹ lẹ́sẹkẹsẹ 


Dandan ni fún Ọjọgbọn láti ni atude n'ile, bẹ́ẹ̀ni a sì gbọ́dọ̀ máa lo lorekore. 


Hnmmm..... O se pàtàkì fún àwọn tí wọn ba fẹ́ràn obìnrin. 


Gbogbo ọjọ́ tí oògùn kii sisẹ lára rẹ, ẹ jẹki a lọ gbìyànjú àwọn atude yìí. 


1. Ìgbẹ́ adiẹ ibilẹ inú kúkú tàbí (cage) 

2. Eepo ọbọ 

3. Ọṣẹ dúdú 


 *Sise rẹ :* 

Ao sá ìgbẹ adìẹ yẹn tí yóò gbẹ dáadáa, ao wa gun mo eepo ọbọ, ao gùn papọ mọ ọsẹ dudu. 


Ao máfi wẹ ni ararọ.

No comments:

Post a Comment